Ìgbéyàwó ìbíle ní Ilẹ̀ Yorùbá jẹ́ àsìkò ti ẹbí ọkọ àti ì̀yàwó ma nparapọ. Ìyàwó ṣíṣe ni ilẹ̀ Yorùbá kò pin sí ãrin ọkọ àti ìyàwó nikan, ohun ti ẹbí nparapọ ṣe pẹ̀lú ìdùnnú nípàtàkì lati gbà wọ́n níyànjú àti lati gba àdúrà fún wọn.
A lè ṣe gbogbo ètò ìgb́eyàwó ìbílẹ̀ ni ọjọ́ kan tàbí ọjọ́ púpọ̀ fún àpẹrẹ: mọ̀mí-nmọ̀ẹ lọjọkan ati idana lọ́jọ́ keji tàbi ọjọ miran. Ní ayé àtijọ́, nígbàtí Yorùbá ma nṣe ayẹyẹ níwọ̀ntúnwọ̀sín, ilé ẹbí tàbi ọgbà bàbá àti ìyá iyawo ni wọn ti nṣe ayẹyẹ ìgbéyàwó, ṣùgbọ́n láyé òde òní, àyè ọ̀tọ̀ bi ilé ìlú, pápá ìṣeré, ilé àlejò àti bẹ̃bẹ lọ ni wọ́n nlo. Àṣà gbígba àyè ọ̀tọ tógbòde bẹ̀rẹ̀ nítorí àwọn adigun jalè àti àwọn ènìyàn burúkú míràn ti o ma ndarapọ pẹ̀lú àwọn àlejò tí a pè sí ibi ìyàwó lati ṣe iṣẹ́ ibi. Owó púpọ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ma nfi gba à̀yè ibi ṣíṣe ìyàwó.
Bí òbí ba ti lọ́lá tó ni wọn ma náwó tó, nitori ìdùnnú ni fún òbí pé a tọ́mọ, wọ́n gbẹ̀kọ́, wọn fẹ di òmìnira lati bẹ̀rẹ̀ ẹbí tíwọn, ṣùgbọ́n àṣejù ati àṣehàn ti wa wọ́pọ̀ jù. Nítorí ìnáwó ìgbéyàwó, ilé ayẹyẹ pọ̀ju ilé ìkàwé lọ láyé òde òní. Kí ṣe bi a ti náwó tó níbi ìgbéyàwó lo nmu àṣeyorí ba ọkọ àti ìyàwo, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ntuka láìpẹ́ lẹ́hin ariwo rẹpẹtẹ yi. Yorùbá ni “A ki fọlá jẹ iyọ̀”, nínú ìṣẹ layika ni ilẹ̀ Aláwọdúdú, ó yẹ ki a ṣe ayẹyẹ ìgbéyàwó níwọ̀ntúnwọ̀nsìn. Ẹ fojú sọ́nà fún ètò ìgbéyàwó ibilè
Version française
Le mariage traditionnel en pays Yoruba est une période au cours de laquelle le marié et la famille de la mariée se rencontrent et il ne s’agit pas simplement d’une affaire entre les mariés. C’est un événement joyeux qui rassemble les deux familles pour qu’elles conseillent et prient pour les futurs mariés.
Toutes les cérémonies de mariage peuvent se dérouler en un jour ou s’étaler sur plusieurs jours, comme à l’époque où l’introduction de la famille se faisait souvent un jour alors que le mariage traditionnel devait avoir lieu à une autre date. Dans les temps anciens, lorsque les mariages yoruba étaient le plus souvent pratiqués avec modération, la cérémonie se déroulait dans la maison familiale ou chez la mère de la mariée. Mais de nos jours, les cérémonies de mariages se déroulent principalement dans un lieu loué, comme une salle communautaire, un terrain de sport, un hôtel, etc. etc. La culture de location d’un lieu neutre a commencé à la suite d’attaques de voleurs à main armée et d’éléments sans scrupules infiltrant les invités pour causer des dégâts considérables. Ces sites sont souvent sécurisés avec beaucoup d’argent.
La richesse des parents détermine souvent à quel point le mariage peut coûter cher, parce que le fait que des enfants aient été formés et qu’ils souhaitent maintenant être indépendants pour fonder leur famille est une source de joie, mais il y a maintenant beaucoup d’excès et de folie. En raison du coût énorme du mariage, il y a plus de salles de lieux de fêtes que de bibliothèques. Et pourtant, ce n’est pas le coût d’un mariage qui en fait le succès, car de nombreux mariages sont dissous presque immédiatement après les cérémonies. Un proverbe yoruba dit que «le sel n’est pas consommé en fonction de la richesse». Dans une Afrique où sévit la pauvreté, il est préférable de procéder à des cérémonies de mariages modérées