Les Industries Créatives Africaines Boostées d’un Demi-Milliard de Dollars par les Grandes Banques

blog1

Les Industries Créatives Africaines Boostées d’un Demi-Milliard de Dollars par les Grandes Banques


Ilẹ̀-Adúláwọ̀ rí àbọ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún-lọ́nà-ẹgbẹ̀rún owóo dollar láti ọ̀dọ̀ Ilé-ìfowópamọ́sí ńláńlá fún ìgbéfúkẹ́ Iléeṣẹ́ ọgbọ́n àtinudá

Àwọn ọlọ́gbọ́n àtinudá Ilẹ̀-Adúláwọ̀ gbọdọ̀ ‘ká èso ọrọ̀ tí ó pọ̀ tí ó ń dúró fún kíká’

Ó ti pẹ́ tí àwọn iléeṣẹ́ ìgbélárugẹ àṣà àti ọgbọ́n àtinudá ti ń ṣe ohun mèremère ní ti ìdàgbàsókè ọrọ̀ Ajé, ní ti ipa tí wọ́n ń kó àti agbára tí ó wà níkàáwọ́ wọn láti mú àyípadà dé bá àwùjọ àti ìpàṣípààrọ̀ àṣà.

Lọ́dún-un 2013, iléeṣẹ́ ìgbélárugẹ àṣà àti ọgbọ́n àtinudá (CCI) rí owó ẹgbẹẹgbẹ̀rún-lọ́nà-ẹgbẹ̀rún 2,250 dollar ti Ìṣọ̀kan Orílẹ̀-èdèe Amẹ́ríkà àti iṣẹ́ tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún 29.5 kárí ayé [àmọ́] ìdá 3 àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí wá láti Ilẹ̀-Adúláwọ̀ àti Àárín gbùngbùn Ìlà-Oòrùn tí ó jẹ́ agbègbè àwọn aráa Lárúbáwá, ìyẹn gẹ́gẹ́ bí ìwádìí àyẹ̀wò fínnífínní Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé fún Ẹ̀kọ́, Ìwádìí Ìjìnlẹ̀ àti Àṣà (UNESCO) ọdún-un 2013 tí a pè ní “Àsìkò Àṣà” kan ti ṣe fi hàn.

Torí ìdí èyí, Ilé-ìfowópamọ́sí Ọjà títa sókè òkun-àti-kíkó ọjà wọlé (Afreximbank) pẹ̀lú àbáṣepọ̀ọ UNESCO àti Ẹgbẹ́ Ilé-ìfowópamọ́sí Ìdàgbàsókè Ilẹ̀-Adúláwọ̀, ṣe àgbékalẹ̀ Ìpàṣípààrọ̀ Ọgbọ́n Àtinudá Ilẹ̀-Adúláwọ̀ – Creative Africa Exchange (CAX)  tí yóò “dúró gẹ́gẹ́ bíi ohun tí yóò ṣe àmúpapọ̀ àwọn nǹkan ọrọ̀ àti àlùmọ́nì tí ó wà nínú iléeṣẹ́ ọgbọ́n àtinudá” tí yóò ṣe àgbéró, mú owó wọlé àti lapa rere lára àwọn ọlọ́gbọ́n àtinudá àti àwọn oníṣẹ́ àṣà, bí ibùdó ìtakùn àgbáyé CAX ṣe ní i lákọsílẹ̀. Ọdún-un 2018 ni ìfilọ́lẹ̀ CAX wáyé ní ibi Ìpàtẹ Ọjà Inú Ilẹ̀-Adúláwọ̀ ní ìlúu Cairo, orílẹ̀-èdèe Egypt, nínú oṣù Ọ̀pẹ̀ ọdún-un 2018.

a ti bèbèlo

copyright5