Ní ayé àtijọ́, Òjò àti Iná jùmọ̀ ń du obìnrin kan láti fi í ṣaya. Nígbà tí ọjọ ìgbéyàwó pé wọ́n fa ọmọ sí ìta gbañgba. Wọ́n sì sọ pé ẹni bá ti lágbára jù nínú awọn méjéèjì ni ki ó fi í ṣaya. Iná ló kọ́kọ́ dé. Ó sì ki ọmọ mọ́lẹ̀, ó ń gbé e lọ. Òjò sì ti ṣú kẹlẹkẹlẹ. Ọmọbìnrin náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ orin báyìí pé: Iná o, ọ̀rara. Aráńta Iná pupa bẹ́lẹ́jẹ́ Aráńta Òjò dúdú bọ̀lọ̀jọ̀ Aráńta Kàkà ñ fẹná ma fójò Aráńta Òjò lọkọ àgbàdo Aráńta Òjiijì ni òjò bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀, Ó pa iná kú pátápátá. Ó si gbé ọmọbìnrin náá lọ.