Obasanjọ-Kufuor : AU, ECOWAS gbọdọ̀ dá sí ọ̀rọ̀ Benin

blog1.jpg

Aarẹ nigba kan ri lorilẹede Ghana, John Kufuor ati Aarẹ tẹlẹ ni Naijiria Olusẹgun Ọbasanjọ, ti ke pe ajọ iṣọkan awọn orilẹede ni Afirika (AU), ati ajọ ECOWAS, lati da si oṣelu orilẹede Benin to n kọni lominu bayii. Ninu atẹjade kan ti Obasanjo ati Kufuor jijọ gbe sita, eyi ti agbẹnusọ Obasanjo, Kehinde Akinyemi fi tẹ BBC Yoruba lọwọ, awọn agba Afirika naa ni asiko ti to lati da si ọrọ oselu Benin ko ti di yanpọn-yanrin. Wọn ṣalaye wi pe, idibo to waye ni orilẹede Benin ni ọjọ Kejildinlọgbọn oṣu Kẹrin ọdun 2019, ninu eyi ti wọn ko jẹ ki awọn ẹgbẹ alatako ti kopa, jẹ ohun to tẹ ẹtọ awọn aarẹ ana lorilẹede Benin, Boni Yayi ati awọn olori ẹgbẹ alatako to ku mọlẹ.

Kufuor ati Obasanjo ni, bo tilẹ jẹ pe ọrọ idibo jẹ ohun ti tẹru-tọmọ yẹ ko pa, amọ ohun to n ṣẹlẹ ni Benin ko ri bẹẹ.

Nitori naa, wọn n gba awọn olori orilẹede to wa ni Afirika ni imọran wọn yii:

Igbesẹ to yẹ kawọn olori Afirika gbe lori ọrọ Benin:

  • Ki AU ati ECOWAS gbe igbimọ dide lati lọ rọ Aarẹ Talon ti orilẹede Benin, ko le jẹ ki aarẹ ana lọ gba iwosan ni oke okun
  • ECOWAS ati AU gbọdọ gbe igbesẹ lati ri pe ọrọ naa ko bajẹ kọja ibi to de yii
  • Orilẹede Benin gbọdọ ri wipe ijọba awa-arawa tootọ fidi mulẹ.

ibinimori

copyright5