Lagos : ìjà laarin Gómìnà Àmbọ̀dé àti Bàbá Òṣèlú rẹ, Gómìnà tẹ́lẹ̀ Bọ́lá Tinubu

blog1

Ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ yan ẹni ti yio du ipò fún ẹgbẹ́ kò yẹ kó fa ìjà laarin Gómìnà Àmbọ̀dé àti Bàbá Òṣèlú rẹ, Gómìnà tẹ́lẹ̀ Bọ́lá Tinubu – La primaire directe pour le choix du candidat APC à l’élection du Gouverneur ne devrait pas provoquer une rupture entre le gouverneur Ambode et son parrain politique, l’ex gouverneur Bola Tinubu.

Nínú gbogbo ẹgbẹ́ òṣèlú orílẹ̀ èdè Nigeria, àwọn alágbára díẹ̀ nínú ẹgbẹ́ ni ó ńyan ẹni ti wọ́n fẹ́ ki o fi iga gbága fún ipò pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú yoku.  Ó ti di àṣà ki Gómìnà Èkó lo ọdún mẹrin nigbà méji tàbi ọdún mẹjọ lóri ipò Gómìnà.  Lati ìgbà òṣèlú alágbádá kẹrin ti ó bẹ̀rẹ̀ ni ọdún kọkàndínlógún sẹhin ni orílẹ èdè Nigeria, ni ìpínlẹ̀ Èkó ti yan Bọ́lá Ahmed Tinubu si ipò Gómìnà.  Ìpínlẹ̀ Èkó fẹ́ràn Bọ́lá Tinubu, èyi jẹ́ ki ó di ẹni àmúyangàn fún gbogbo ẹgbẹ́ òṣèlú ti ó wà, nitori èyi ẹni ti ó bá fi ọwọ́ si, fún ipò òṣèlú ni àwọn èrò ìpínlẹ̀ Èkó mba fi ọwọ́ si.

Lẹhin ọdún mẹjọ ti Gómìnà tẹ́lẹ̀ Bọ́lá Tinubu pari àsìkò tirẹ̀, fún àìdúró iṣẹ ribiribi ti ó ṣe ni ìpínlẹ̀ Èkó, ó pẹ̀lú àwọn ògúná gbòngbò òṣèlú ti ó yan Gómìnà Babátúndé Rájí Fáṣọlá ti òhun naa lo ọdún mẹjọ. Gẹ́gẹ́ bi bàbá àgbà òṣèlú, Bọ́lá Tinubu da òróró si orí Gómìnà Àmbọ̀dé, èyi jẹ́ ki ó mókè ju gbogbo àwọn ti ó du ipò àti di Gómìnà ni ọdún kẹta sẹ́hìn, ti ó si fa ọ̀tá laarin ẹgbẹ́ àti àwọn ti ó du ipò Gómìnà fún Bọ́lá Tinubu.

ibinimori

Le Yoruba Devient Langue Officielle au Brésil

Nigeria : Distribution d’une Traduction de la Constitution en Yoruba …

copyright5

Publicités

Répondre

Entrez vos coordonnées ci-dessous ou cliquez sur une icône pour vous connecter:

Logo WordPress.com

Vous commentez à l'aide de votre compte WordPress.com. Déconnexion /  Changer )

Photo Google

Vous commentez à l'aide de votre compte Google. Déconnexion /  Changer )

Image Twitter

Vous commentez à l'aide de votre compte Twitter. Déconnexion /  Changer )

Photo Facebook

Vous commentez à l'aide de votre compte Facebook. Déconnexion /  Changer )

Connexion à %s